Àpèké Ojúloge(episode 1)
(Àbíké nba Àpèké tii se omo rę soro, o ti to bi òsę dię ti Àbíké ti n gbiyanju lati je ki Àpèké ma kiri oja sugbon ti Àpèké ni dandan la, ise office ni oun ma a se ni t'oun. Àpèké kuku ti pari University ti o si ti sinruulu sugbon, ojoojumo lo fi n pa pali mo egbe bi iye adie ti ko si ri ise kan pato.)
Abike:- Mi o saa le ri igbo nile, kin wa ni ko t'ori bò ó ati wipe okan mi o ki n tan mi ję.
Àpèké :- Ę wo, igbo aginju ti o to eleyi o si, ti mo ba gbe igba oja ti mo bere si i kiri oja, oju wo ni ki awon enia fi ma a wo mi? University graduate for that matter.
Àbíké:- Dakun Àpèké, omo o ni ko oro si iwo naa lenu. (Àbíké fe ma a kunlę fun Àpèké)
Àpèké:- Maami, mi o like ę o, Ę kan fe fi oro yii somí lenu ni, emi Àpèké ojuloge funra mi, ki n maa kiri oja(O taka Sori) never! O d'aiye atunwa.
Àbíké:- Aiye to wa yi naa ni waa ti kiri, kii se aiye atunwa kankan. Ayafi ti kii ba se emi ni mo bi o loku. T'o ba si gbo oun ti mo n ba ę so nse ni ma a fi omu aya mi t'omu gbe o sepe (Bi Àbíké se so oro yii ni Àdìsá tii se aburo baba Àpèké de bawon lęnu ę. Lati igba ti Àpèké ti wa ni omo odun perete ni baba re ti ję Eledumare nipe)
Àdìsá:- Ha ha ha ha, Iya Àpèké, kin ni O n ba omo yii fa to fi di ologun a nfi omu sepe?
Àpèké:- (O n jan ęsę mo'lę soro) Ę ję bawon soro ki won fi mi lorun silę, ajębę!
Àbíké:- Ajębę kinni? (Àpèké binu jade niwaju awon mejeeji) Ę wo bi Àpèké se n binu kuro niwaju mi, Àpèké, o fę gba epe.
Àdìsá:- A ni ko ma a se suuru, ehn? Suuru nikan ni oro awon omo ode isęyi gba. Ki gan_an lo sęlę gan? (Awon mejeji joko sori aga kan ti ko fi bęę lalubarika)
Àbíké:- Ę seun baba oko mi, lati bii odun meji ti Àpèké ti jade ile_iwe giga, nse ni o nfi ojoojumo wa isę. Mo si gba omo mi ni imoran wipe, dipo ki o ma a fi ęsę gba'lę kiri adugbo, ko se kuku ma a kiri oja. Kinni mo so eyi fun? Nse ni Àpèké n gbo mi lęnu.
Àdìsá:- ( O nsoro pęlu iyalęnu) k'o ma a kiri oja?
Àbíké:- Ęhn
Àdìsá:- Pęlu ojo ori Àpèké yi ati gbogbo iwe to ka. Sugbon, to ba ti ę fę ba a so gan, kii se pęlu agidi. O kan ję wipe, emi o lero wipe o ba oju mu ni.
Àbíké:- Bayi ni ma se nkan mi, ko yi pada ( Àbíké kunlę si iwaju Àdìsá) Baba oko mi, ę se ję ki a pa owo po lati fi omo yii s'ona.
Àdìsá:- Ona oja kikiri?
Àbíké:- ( O nsoro pelu ohun iręlę) Bęę nii, o damiloju wipe yio si di isę gidi fun_un.
Àdìsá:- T'o ba ri bęę, pe Àpèké wa fun mi ki nba soro boya a ję gbo si mi lęnu.(Àbíké sare wole lati pe Àpèké fun Àdìsá. O wa gbogbo inu ile sugbon ko kęfin Àpèké rara)
Àbíké:- O ninu fufu gbaa ni omo Àpèké yi o, nję ę ję mo wipe o ti binu jade.
Àdìsá:- Ko buru, ni mo ni ko yo'ju si mi t'o ba de. (Àdìsá dide, o gbon fila ę pę pę pę, o fę ma a lo) Mo fę lo mu ęmu ni ojude tęlę ni mo gbo ariwo iwo ati omo rę, mo fę lo bu nkan s'aya. (Àdìsá n jade lo)
Àbíké:- Ę se gan an ni baba oko mi, ma a jisę yin fun t'o ba de, kę ba mi fi ogbon agba s'alaye oro na a fun.
(Leyin wakati dię ti Àdìsá bo sita ni Àpèké wole wa. Àbíké ti rękę silę de e. Bi o se n wole ni Àbíké pakuru mo o. )
Abike:- Ko rada rada rę bo sibi yi. Nbo lo gba lo?
Àpèké:- Odo Sadé ni mo lo.
Àbíké:- (gbogbo oju ę ti pon kan kan kan) Àpèké, mo pe o ni gba n gba ati koro sugbon o lo o ni gboro. Ęhn, t'o o ba gba lero, se bi o gba ni tipa-ti-kuku. (Àbíké fa obę yo lati igun kan lęgbę ibi t'o joko si. Kinni Àpèké ri obę si, nse ni o ba ęsę rę soro. Àbíké naa tu kękę ere silę tę le e. Bi Àpèké se n sare l'o n pariwo, maami maami, obę. Gbogbo ara adugbo ę gba mi o, somebody help. Nibiti Àpèké ti n sare lo ni o ti fi ęsę ko itakun ti o si subu. Àbíké sun moo, o fa obę yo.
TO BE CONTINUE.
Wednesday, 21 June 2017
New
ÀPÈKÉ OJULOGE

About The Announcer
SoraTemplates is a blogger resources site is a provider of high quality blogger template with premium looking layout and robust design. The main mission of SoraTemplates is to provide the best quality blogger templates.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment