Àpèké ojuloge episode 2 - The Announcer

Breaking

Windows

BANNER 728X90

Monday, 26 June 2017

Àpèké ojuloge episode 2


( Ariwo ni Àpèké pa to fi laju saye.  Asee orun  lO gbe e lo lodo Sade ore re to sa a lo)
Àpèke: - (O p'ose)  Ala ni sa.
Sade: -  Ala ni kinni?
Àpèke: - Ma a wo ni ti ę, nse ni mo ri Maami ti won nfi obę le mi kiri Loju orun
Sadé :- Se lori oro t'o s'alaye fun mi naa ni?
Àpèké :- Ma damilohun. Nse ni mo gbe oro na a sokan sun lo (Àpèké tun ijoko jo daada) Ęhn Ęhn Sadé, mo ngbo ohun okunrin kan lati Oju orun, se ala niyen na a ni?
Sadé :- Àpèké alala, Kii se ala o, ohun Fęmi ni oun gbo yęn
Àpèké :- Sadé ma gbabode fun mi Lori oro Fęmi yi o
Sadé :- Ki gan ni o fa ti o kii fe ri imi Fęmi Laatan gan? Se bii (Àpèké ja oro gba mi Sadé lęnu)
Àpèké :- Se bii Kinni? Se dandan ni won fi n fę enia ni, ati wipe Fęmi ti a n soro rę yi gan yii, ko ni isę kan pato ti o le fi bò ara rę.
Sadé :- (O bu sęrin, o f'owo gbe Àpèké lękę jo) Àpèké ojuloge orę mi atata, o dabi ęni wipe o ti fę ma a yo ifę Olóyè Sáálíù ( Kinni Àpèké gbo eyi si nse ni o faraya)
Àpèké :- A!  Sadé, Oju gba mi ti fun ę,  kii dę se ębi ę, ti mi o ba joko iranu si odo ę ni, o ni ma a fi ęgbin buruku Lo mi. ( Àpèké fi ibinu silękun lati ma a ba ti ę Lo. B'ose silękun Lo pade Fęmi ni ęnu ona ti iyęn pa kękę mo)
Fęmi :- Àpèké ololufę mi, kaasan.
Àpèké :- Fęmi, Ę melo ni mo ti so fun Ę wipe ko ma ma a pe mi ni ololufę ę mo?  O dę mo mi Lana ki o to d'oni. Fęmi wa kan abuku.
Fęmi :- Oro yii o fa ija rara ati wipe danwo Lo bi Iya okęrę, ko si nkan mii to ję ki n maa tęle ę kiri ju ifę ti mo ni si Ę Lo.
Àpèké :- (O pa atęwo ęlęya mo Fęmi) Se iru ę l'oyę ko ma a nifę obinrin? Iwo ti o o tii mo ibiti agbami - aiye n gbe ę Lo. Jo mi o raye ęjo Osi. ( Àpèké p'ose mo Fęmi, o fi Oju gbe e lati oke, ona a mo'lę. Àpèké gba ona ile Lo. Sadé jade si Fęmi Nibiti o ti nwo bi ęni ti ojo pa elubo mo lowo)
Sadé :- Fęmi, wa a ni lati se opolopo suuru ni o. Iyęn to ba ję wipe Otito ni o ni'fę Àpèké.
Fęmi :- Mo ni'fę Àpèké sugbon, awon iwa to ma n hu yii na a ni wahala sugbon, o damiloju wipe dun-dun ni osan ma a so. ( Sadé sin Fęmi s'ona lęyin ti won soro tan.)

    ( Bi Àpèké se de ęnu ona ile won ni ęru Àbíké Iya rę ti n ba, nitori o mo wipe baba nla were kan ni. O fi okan kan wole. B'ose sunmo Àbíké ni ori obę lowo ę, ęru baa nitori ala ti o la lodo Sadé, o n sunmo ęyin pada dię dię)
Àbíké :- Ęni ti wa a solęnu Lo nwa, lati igba ti o ti kuro ninu ile, emi ati baba oko mi wa gbogbo inu ile sugbon o ti salo.
Àpèké :- Iya Àpèké o, Ę ma binu si mi, se ę ti Jęun abi ki n sare ba yin se eto nkan ti ę ma a ję?
Àbíké :- Ma ti ę seyonu, nse ni ko tete gba odo aburo baba ę Lo.
Àpèké :- Se kii se Lori oro yi ni won tun fę ri mi fun?
Àbíké :- Sa a lo ba a. Se bi molębi baba rę ni, ęyin si l'ęjo ni ara yin
Àpèké :- Se ki n wa ma a lo bayi ni?
Àbíké :- Ki Lo tun fę ma a duro de, Iwo gan ni won n duro de nile.  ( Àpèké bo s'ona lati Lo ba Àdìsá. Afi bi ęni wipe nse ni Olóyè Sáálíù n duro ki Àpèké ba tię lo k'onle e wole ni. Olóyè Sáálíù paaki  oko ayokęlę t'ogbe wa si iwaju ile awon Àpèké. Olóyè Sáálíù lowo bii sękęrę, to bęę gę ti ko o fę si ęnikan-kan t'o le baa figa-gbaga laarin awon ti won di jo n rin. Ko se owoo koko, bęę si ni ko bawon lowo ninu epo roobi, kii dę se oloselu. Burędi tita nikan ni ojulowo isę ti Olóyè Sáálíù Yan laayo ti o si mu ni òkúnkúndùn. O sokalę lati Lo ba Àbíké tii se Iya Àpèké.)
Àbíké :- B'ose n gbo iro ęsę, o ro wipe Àpèké ti pada Lona ni) Àpèké, se bi mo so fun o wipe iwo ni aburo baba rę n duro de?
Olóyè Sáálíù :- ( O kan ilękun gbin gbin gbin) Ę nlę nile yi o.
Àbíké :- (O silękun fun Olóyè Sáálíù) Ę o tię sofun wa wipe ę Nbo,  ęyin odidi Olóyè.
Olóyè Sáálíù :- Ęgun t'o gun mi lęsę Lo ję ki n maa se  laka-laka to alabę Iya Àpèké lo.
Àbíké :- Ęgun bii ti bawo?
Olóyè Sáálíù :- Wo o Iya Àpèké, o dabi ęni wipe Iwo gan an l'o fę fi Àpèké silę lati ma a tęle mi lo s'ilu eko.
Àbíké :- Rara o, mi o ję da iru aso bęę s'oro ati wipe n o Lee fi Oju olore mi gun'gi lai lai. Ah ah ah, l'aduru ore banta-banta tę ti nse fun mi lati igba ti Àpèké ti wa ni ile-iwe alakobęrę titi t'o fi ka'we gb'oye. O kan ję wipe...........
Olóyè Sáálíù :- (Olóyè Sáálíù gba oro  mo Àbíké lęnu) O kan ję wipe o le e fi omo rę fun agbalagba bii t'emi, Abi?
Àbíké :- Rara o, sebi ę fę lo da lokowo ni?
Olóyè Sáálíù :- Ęhn, ki wa Lo fa idena lati igbayi wa?
Àbíké :- Àpèké ni o, gbogbo ojo ni Mo fi n ję oro yii lęnu sugbon nse Lo ma a nfi aake kori wipe ko s'oun to jo.
Olóyè Sáálíù :- Ehn to ba ri bęę, ojo t'aba ri'bi gan lo yę k'o wo'lę. Loni yii gan an ni ma a mu Àpèké lo si ilu eko, ko ni d'ola, tię ni ko saa ti f'owo si.
Àbíké :- Ę maa gbo baba Olóyè, owo nikan ko ni mo fi sii, gbogbo ara ni mo fi luu l'ontę.        
Olóyè Sáálíù :- ( Olóyè Sáálíù ni ki Àbíké tęle oun de idi oko ni'ta. Bi won se de idi oko ni'ta ni Olóyè na owo mu nkan ninu oko, o fi le Àbíké lowo) Ęgberun Lona aadota Naira niyęn.
Àbíké :- Tani kin nlo ba yin ko o fun?
Olóyè Sáálíù :- (O tun agbada orun rę se daada) Iwo Lo ni gbogbo ę.
Àbíké :- (O kunlę si iwaju Olóyè Sáálíù) N o tię mo oun ti ma a so mo. Ę wo o, mo fi Àpèké fun yin, mo jowo ę tokan tokan.
Olóyè Sáálíù :- (O ta'ju kan, o ri Àpèké ati Àdìsá ti won nbo lat'oke rere) Àpèké naa l'o n bo yęn
Àbíké :- Odo aburo baba ę ni mo tii lo nigbati ko fę gbo oun ti mo n ba so nipa oro yin. O damiloju wipe oro ti jasi ibi're ni awon mejeeji fi n bò.
Olóyè Sáálíù :- (O ręrin musę) Mba jo, mba yo o. ( Àpèké ati Àdìsá rin sun mo odo won. Àpèké ki Olóyè Sáálíù ni iki omoluabi, won kii kuku se ajeji arawon mo. Olóyè o besu bęgba rara) Àpèké wo'le Lo ko ęru rę jade, L'oni yii gan an ni wa a lo bęrę isę ti Iya ę nba ę so. (Àpèké o wi nkan kan le oro Olóyè Sáálíù, ere buruku lo sa wo'nu ile lo ti oju rę le koko bi t'odaran. )
      TO BE CONTINUE.



No comments:

Post a Comment